Wọ́n ti ṣe àìdáa sí mi, wọ́n sì ti fojú di mí ní South Africa — Chidimma Adetshina


Chidimma Adetshina: South Africa ni wọ́n bí mi, wọ́n sì ṣe àìtọ́ sí mi

Ayaba ẹwà, Chidimma Adetshina, ẹni tí àwọn aláṣẹ South Africa ń gbìyànjú láti lé kúrò ní orílẹ̀-èdè náà, ti sọ pé South Africa ni wọ́n bí òun, ó sì gbà pé àwọn aláṣẹ ti ṣe àìtọ́ sí òun, tí wọ́n sì fojú kọ ọ̀ràn rẹ̀.

Àwọn aláṣẹ South Africa ń tẹ̀síwájú nínú ìgbésẹ̀ láti lé Adetshina kúrò ní orílẹ̀-èdè náà lẹ́yìn tí wọ́n sọ ní ọdún 2024 pé ó jẹ́ ẹni tí kò ní ìwé àṣẹ tó yẹ láti gbé níbẹ̀.

Adetshina, ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n, ní baba ọmọ Nàìjíríà àti ìyá ọmọ Mozambique. Wọ́n fagilé àwọn ìwé ìdánimọ̀ rẹ̀ ní South Africa lẹ́yìn tí àwọn ìbéèrè dìde nípa ọmọ orílẹ̀-èdè rẹ̀ nígbà tó ń kópa nínú ìdíje Miss South Africa ní ọdún 2024.

Lẹ́yìn náà, ó fi South Africa sílẹ̀, ṣùgbọ́n wọ́n mú un ní oṣù Kẹfà ọdún yìí lẹ́yìn ẹ̀sùn pé ó tún wọ orílẹ̀-èdè náà lọ́nà tí kò bófin mu. Wọ́n sì tú u sílẹ̀ lẹ́yìn ìkìlọ̀.

Ìgbẹ́jọ́ nípa ìgbìyànjú láti mú un wà ní àtìmọ́lé ni wọ́n sún síwájú títí di ọdún tó ń bọ̀ lẹ́yìn ìgbẹ́jọ́ kan ní Cape Town ní ọjọ́rú.

Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ lẹ́yìn ìgbẹ́jọ́ náà, Adetshina sọ pé ó dà bí ẹni pé àwọn aláṣẹ South Africa fẹ́ lo ọ̀ràn rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ.

Ó ní:

“Mo fẹ́ rán gbogbo ènìyàn létí pé South Africa ni wọ́n bí mi. Mo ti fi ẹ̀bẹ̀ sílẹ̀ nípasẹ̀ àwọn ọ̀nà òfin tó yẹ láti mọ ipò mi àti ọmọ orílẹ̀-èdè tí mo jẹ́.”

Ayaba ẹwà náà tún sọ pé kò yẹ kí ìkórìíra àwọn àjèjì àti àìtọ́ pinnu bí wọ́n ṣe ń bá àwọn ènìyàn lò, níbi tó ti hàn pé ó ń tọ́ka sí àwọn alátakò tó péjọ síta ilé ẹjọ́ láti béèrè pé kí wọ́n lé e kúrò ní orílẹ̀-èdè náà.

Ẹgbẹ́ ajìjàgbara March and March ló ṣètò ìfihàn náà. Ẹgbẹ́ náà ti ń ṣe ìpolongo pé kí àwọn àjèjì tí kò ní ìwé àṣẹ tó bófin mu kúrò ní South Africa. Àwọn alátakò kan tún lépa ọkọ̀ Adetshina nígbà tó ń jáde kúrò nílé ẹjọ́.

Adetshina, tó ń kẹ́kọ̀ọ́ òfin nígbà yẹn, fi South Africa sílẹ̀ ní ọdún 2024. Lẹ́yìn náà, ó kópa nínú ìdíje Miss Universe Nigeria lẹ́yìn tí àwọn olùṣètò pè é, ó sì gba oyè náà.

Nígbà ìgbẹ́jọ́ ọjọ́rú, Ẹ̀ka Ọ̀rọ̀ Ilé ti South Africa jiyàn pé Adetshina ti béèrè fún ìwé àṣẹ láti wọ South Africa nígbà tó wà ní Nàìjíríà, àti pé ó ti gba ìwé ìrìnnà Nàìjíríà fún ara rẹ̀ àti ọmọ rẹ̀.

Adetshina, ní apá tirẹ̀, ti tẹ̀síwájú láti sọ pé South Africa ni ilé òun.

Wọ́n ti sún ẹjọ́ náà sí oṣù Kejì ọdún 2027 láti jẹ́ kí ìpèníjà òfin rẹ̀ sí ìpinnu Ẹ̀ka Ọ̀rọ̀ Ilé láti lé e kúrò ní orílẹ̀-èdè náà lè tẹ̀síwájú. Ó sì wà ní òmìnira nígbà tí ọ̀ràn náà ń lọ.

Wọ́n fagilé ìwé ìdánimọ̀ àti ìwé ìrìnnà rẹ̀ ní South Africa ní ọdún 2024 lẹ́yìn ẹ̀sùn pé ìyá rẹ̀, Anabela Rungo, lo ìdánimọ̀ ẹlòmíràn lọ́nà àìtọ́ láti gba ọmọ orílẹ̀-èdè South Africa.

Ìwádìí nípa ọmọ orílẹ̀-èdè Adetshina bẹ̀rẹ̀ lẹ́yìn tó di ọ̀kan lára àwọn tó dé ìpele tó ga jù nínú ìdíje Miss South Africa. Àwọn ìbéèrè sì bẹ̀rẹ̀ sí í dìde nípa ìdílé ìyá rẹ̀ láti Mozambique àti baba rẹ̀.

Nígbẹ̀yìn, ó yọ ara rẹ̀ kúrò nínú ìdíje náà lẹ́yìn tí àríyànjiyàn nípa ọmọ orílẹ̀-èdè rẹ̀ pọ̀ sí i.

Nínú àwọn ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò rẹ̀ tẹ́lẹ̀, Adetshina ti sọ pé Soweto, nítòsí Johannesburg, ni wọ́n bí òun, àti pé ó dàgbà ní Cape Town.

Láti ọwọ́: Adam Mosadioluwa