Àwọn olóṣèlú méjì, Peter Obi àti Omoyele Sowore, ti tako èrò tí Igbakeji Ààrẹ tẹ́lẹ̀, Atiku Abubakar, gbé kalẹ̀ pé òun lè mú ìrànlọ́wọ́ owó ìjọba lórí pétíròòlù, tí a mọ̀ sí subsidy, padà bí wọ́n bá yàn án sípò Ààrẹ ní ọdún 2027.
Peter Obi sọ pé, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ àwọn aráàlú kò tíì rí àǹfààní tó yẹ láti inú owó tí ìjọba sọ pé wọ́n fi pamọ́ lẹ́yìn tí wọ́n yọ subsidy kúrò, òun ṣì gbà pé yíyọ subsidy kúrò jẹ́ ohun tó yẹ. Ó ní ìṣòro tó wà ni bí àwọn ìjọba ṣe ń ṣàkóso àti bí wọ́n ṣe ń ná owó tó wáyé látinú ìgbésẹ̀ náà.
Obi sọ pé dídá subsidy padà kì í ṣe ojútùú sí ìṣòro náà. Gẹ́gẹ́ bí ó ti sọ, ìjọba yẹ kí ó ti ṣe ètò tó dáa láti dín ìnira tí yíyọ subsidy fa kù fún àwọn aráàlú, kí wọ́n sì tún lo owó tó wáyé láti inú rẹ̀ fún àwọn apá pàtàkì nínú ọrọ̀ ajé.
Ó ní ìgbà tí òun ń dije sípò Ààrẹ ní ọdún 2023, òun ti sọ pé bí subsidy bá yẹ kí wọ́n yọ kúrò, ó yẹ kí wọ́n ṣe é ní ọ̀nà tó ṣètò dáadáa, kí owó tí wọ́n bá rí lè lọ sí àwọn iṣẹ́ tó máa ṣe àǹfààní fún gbogbo àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè.
Ní ọwọ́ kejì, Omoyele Sowore náà tako èrò pé kí Nàìjíríà padà sí subsidy àtijọ́. Ṣùgbọ́n ó ní ọ̀rọ̀ náà kò yẹ kí a wo láìbéèrè pé, ta ni gan-an ti ń jèrè nínú ètò yíyọ subsidy náà?
Sowore sọ pé ìjọba ti ń sọ ní ọ̀pọ̀ ọdún pé wọ́n máa yọ subsidy pétíròòlù kúrò, ṣùgbọ́n ìṣòro tó fa ìjàmbá àti ìṣòro nínú ètò náà kò tíì ní ojútùú tó péye. Ó tún sọ pé àwọn aráàlú, pàápàá àwọn aláìní, ló ń ní ìrora jù lọ nítorí iye owó ọkọ àti ìgbésí ayé tó ń pọ̀ sí i.
Ní báyìí, ìfẹ́ Atiku láti mú ètò kan tó máa jẹ́ kí pétíròòlù rọrùn àti pé owó rẹ̀ má ga ju ti àwọn aráàlú lè ra lọ ti fa ìjíròrò ńlá nínú ilẹ̀ Nàìjíríà.
Àmọ́, agbẹnusọ fún ìpolówó Atiku, Kenneth Okonkwo, ti ṣàlàyé pé èrò Atiku kì í ṣe láti padà sí subsidy àtijọ́. Ó ní ètò náà, tí wọ́n pè ní Atiku Fuel Affordability Plan, dá lórí lílo àwọn ilé ìṣẹ́ ìtún epo inú ilẹ̀ Nàìjíríà àti fífi epo rọ̀ọ̀bì ránṣẹ́ sí wọn ní iye tó yẹ, kí iye owó tí wọ́n fi ń ṣe pétíròòlù lè dín kù, kí pétíròòlù sì lè rọrùn fún àwọn aráàlú.
Nítorí náà, ọ̀ràn subsidy pétíròòlù ti di ọ̀kan lára àwọn ọ̀rọ̀ pàtàkì tó ń fa ìjíròrò nínú òṣèlú ilẹ̀ Nàìjíríà bí ọdún 2027 ṣe ń sún mọ́lé. Àwọn kan fẹ́ kí ìjọba má padà sí ètò subsidy àtijọ́, nígbà tí àwọn mìíràn sì ń béèrè pé kí ni wọ́n ṣe pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ owó tí ìjọba sọ pé wọ́n ti rí láti ìgbà tí wọ́n ti yọ subsidy kúrò?