Ọlọ́pàá Mú Ọkùnrin Ọdún 23 Kan Ní Bauchi Pẹ̀lú Ọ̀pọ̀ Ohun Èlò Tí Wọ́n Fura Sí Pé A Ń Lò Fún Oògùn
Ọlọ́pàá Ìpínlẹ̀ Bauchi ti mú ọkùnrin kan, Aliyu Suleman, ẹni ọdún 23, tí wọ́n fura sí pé ó ní ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú títà àwọn nǹkan olóró àti àwọn ohun èlò tó lè fa ìpalára sí ìlera àwọn ènìyàn.
Gẹ́gẹ́ bí ìsọfúnni tí Ọlọ́pàá Ìpínlẹ̀ Bauchi fi síta, àwọn ọlọ́pàá gba ìgò 64 tó ní Methylene Chloride, tí àwọn kan mọ̀ sí “Suck and Die,” àti ohun tí wọ́n pè ní Rubber Solution mẹ́tadínlógún (17) lọ́wọ́ afurasí náà.
Wọ́n sọ pé ìṣẹ̀lẹ̀ náà wáyé ní agbègbè Bayan Gari, ní ìlú Bauchi, ní ọjọ́ Tuesday, 25 oṣù Kẹjọ, ọdún 2026, ní nǹkan bí ago márùn-ún ìrọ̀lẹ́.
Àwọn ọmọ ẹgbẹ́ ọlọ́pàá láti ẹ̀ka Vehicle Crime Response Unit (VCRU) ni wọ́n ṣe ìgbésẹ̀ náà lẹ́yìn ìsọfúnni tí wọ́n rí. Nígbà tí wọ́n dá afurasí náà dúró, wọ́n ṣe àyẹ̀wò rẹ̀, wọ́n sì rí àwọn ohun èlò náà lọ́wọ́ rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ìkéde ọlọ́pàá.
Aliyu Suleman, tó jẹ́ olùgbé agbègbè Tudun Salmanu ní Bauchi, ni wọ́n ti fi sí àhámọ́ ọlọ́pàá fún ìwádìí síi. Ọlọ́pàá sọ pé wọ́n ti forúkọsílẹ̀ gbogbo àwọn ohun tí wọ́n gba gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí, nígbà tí ìwádìí sí ọ̀ràn náà sì ń tẹ̀síwájú.
Agbẹnusọ Ọlọ́pàá Ìpínlẹ̀ Bauchi, Nafiu Habib, sọ pé ìgbésẹ̀ náà jẹ́ apá kan nínú ìsapá ọlọ́pàá láti dojú kọ ìlò àti títà àwọn nǹkan tó lè ṣe ipalara sí ìlera àwọn aráàlú.
Ọlọ́pàá tún sọ pé afurasí náà ń fọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn olùwádìí, àti pé lẹ́yìn tí ìwádìí bá parí, wọ́n máa gbe ọ̀ràn náà lọ sí ilé ẹjọ́.
Ní ìfèsì rẹ̀, Commissioner of Police ní Ìpínlẹ̀ Bauchi, Sani-Omolori Aliyu, tún tẹnumọ́ pé ọlọ́pàá ti pinnu láti tẹ̀síwájú nínú ìjà sí títà àti lílo àwọn oògùn àti ohun mìíràn tó lè fa ìpalára.
Ó pàṣẹ fún àwọn Area Commanders àti àwọn Divisional Police Officers káàkiri ìpínlẹ̀ náà pé kí wọ́n mú iṣẹ́ ìṣọ́ra àti ìwádìí pọ̀ sí i, kí wọ́n lè tú àwọn nẹ́tíwọ́ọ̀kì àwọn ènìyàn tí wọ́n fura sí pé wọ́n ń tà tàbí ń pín àwọn nǹkan olóró ká.
Ọlọ́pàá tún pe àwọn òbí, àwọn alábòójútó ọmọ àti àwọn olórí àwùjọ láti máa ṣọ́ra, kí wọ́n sì máa fún àwọn ilé iṣẹ́ ààbò ní ìsọfúnni tó yẹ nígbà tí wọ́n bá rí ohun tó lè jẹ́ ìwà ọ̀daràn.
Gẹ́gẹ́ bí ọlọ́pàá ṣe sọ, ìjà sí ìlò oògùn àti àwọn nǹkan tó lè fa ìpalára kì í ṣe ojúṣe àwọn ilé iṣẹ́ ààbò nìkan, ṣùgbọ́n ó nílò ìfọwọ́sowọ́pọ̀ gbogbo aráàlú.
Ìṣẹ̀lẹ̀ náà ti tún fi hàn pé Ọlọ́pàá Ìpínlẹ̀ Bauchi ń mú ìsapá wọn pọ̀ sí i láti dín títà àti ìlò àwọn nǹkan tó lè ba ìlera àti ààbò àwùjọ jẹ. Ní báyìí, ìwádìí ṣi ń lọ, nígbà tí ọlọ́pàá ti sọ pé afurasí náà yóò dojú kọ ìgbésẹ̀ òfin lẹ́yìn tí ìwádìí bá parí.
